Rom 1:27-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Gẹgẹ bẹ̃ li awọn ọkunrin pẹlu, nwọn a mã fi ilò obinrin nipa ti ẹda silẹ, nwọn a mã ni ifẹkufẹ gbigbona si ara wọn; ọkunrin mba ọkunrin ṣe eyi ti kò yẹ, nwọn si njẹ ère ìṣina wọn ninu ara wọn bi o ti yẹ si.

28. Ati gẹgẹ bi nwọn ti kọ̀ lati ni ìro Ọlọrun ni ìmọ wọn, Ọlọrun fi wọn fun iyè rirà lati ṣe ohun ti kò tọ́:

29. Nwọn kún fun aiṣododo gbogbo, àgbere, ìka, ojukòkoro, arankan; nwọn kún fun ilara, ipania, ija, itanjẹ, iwa-buburu; afi-ọrọ-kẹlẹ banijẹ,

30. Asọrọ ẹni lẹhin, akorira Ọlọrun, alafojudi, agberaga, ahalẹ, alaroṣe ohun buburu, aṣaigbọran si obí,

31. Alainiyè-ninu, ọ̀dalẹ, alainifẹ, agídi, alailãnu:

32. Awọn ẹniti o mọ̀ ilana Ọlọrun pe, ẹniti o ba ṣe irú nkan wọnyi, o yẹ si ikú, nwọn kò ṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn nwọn ni inu didùn si awọn ti nṣe wọn.

Rom 1