Rom 1:16-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Nitori emi kò tiju ihinrere Kristi: nitori agbara Ọlọrun ni si igbala fun olukuluku ẹniti o gbagbọ́; fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu.

17. Nitori ninu rẹ̀ li ododo Ọlọrun hàn lati igbagbọ́ de igbagbọ́: gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ṣugbọn olododo yio wà nipa igbagbọ́.

18. Nitori a fi ibinu Ọlọrun hàn lati ọrun wá si gbogbo aiwa-bi-Ọlọrun ati aiṣododo enia, awọn ẹniti o fi aiṣododo tẹ otitọ mọ́lẹ̀:

19. Nitori ohun ti ã le mọ̀ niti Ọlọrun o farahàn ninu wọn; nitori Ọlọrun ti fi i hàn fun wọn.

20. Nitori ohun rẹ̀ ti o farasin lati igba dida aiye a ri wọn gbangba, a nfi òye ohun ti a da mọ̀ ọ, ani agbara ati iwa-Ọlọrun rẹ̀ aiyeraiye, ki nwọn ki o le wà li airiwi:

21. Nitori igbati nwọn mọ̀ Ọlọrun, nwọn kò yìn i logo bi Ọlọrun, bẹ̃ni nwọn kò si dupẹ; ṣugbọn èro ọkàn wọn di asán, a si mu ọkàn òmúgọ wọn ṣókunkun.

22. Nwọn npè ara wọn li ọlọ́gbọn, nwọn di aṣiwere,

23. Nwọn si pa ogo Ọlọrun ti kì idibajẹ dà, si aworan ere enia ti idibajẹ, ati ti ẹiyẹ, ati ẹranko ẹlẹsẹ mẹrin, ati ohun ti nrakò.

24. Nitorina li Ọlọrun ṣe fi wọn silẹ ninu ifẹkufẹ ọkàn wọn si ìwa-ẽri lati ṣe aibọ̀wọ fun ara wọn larin ara wọn:

25. Awọn ẹniti o yi otitọ Ọlọrun pada si eke, nwọn si bọ, nwọn si sìn ẹda jù Ẹlẹda lọ, ẹniti iṣe olubukun titi lai. Amin.

Rom 1