1. PAULU, iranṣẹ Jesu Kristi, ti a pè lati jẹ aposteli, ti a yà sọ̀tọ fun ihinrere Ọlọrun,
2. (Ti o ti ṣe ileri tẹlẹ rí ninu iwe-mimọ́, lati ọwọ awọn woli rẹ̀),
3. Niti Ọmọ rẹ̀, ti a bí lati inu irú-ọmọ Dafidi nipa ti ara,
4. Ẹniti a pinnu rẹ̀ lati jẹ pẹlu agbara Ọmọ Ọlọrun, gẹgẹ bi Ẹmí iwa mimọ́, nipa ajinde kuro ninu okú, ani Jesu Kristi Oluwa wa:
5. Lati ọdọ ẹniti awa ri ore-ọfẹ ati iṣẹ aposteli gbà, fun igbọràn igbagbọ́ lãrin gbogbo orilẹ-ède, nitori orukọ rẹ̀:
6. Larin awọn ẹniti ẹnyin pẹlu ti a pè lati jẹ ti Jesu Kristi:
7. Si gbogbo ẹniti o wà ni Romu, olufẹ Ọlọrun, ti a pè lati jẹ mimọ́: Ore-ọfẹ si nyin ati alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wa wá, ati Jesu Kristi Oluwa.