6. Kọ̀ iwere silẹ ki o si yè; ki o si ma rìn li ọ̀na oye.
7. Ẹniti o ba ba ẹlẹgàn wi, yio gba itiju fun ara rẹ̀, ati ẹniti o ba ba enia buburu wi yio gbà àbuku rẹ̀.
8. Máṣe ba ẹlẹgàn wi, ki o má ba korira rẹ, ba ọlọgbọ́n enia wi, yio si ma fẹ ọ.
9. Fi ẹkọ́ fun ọlọgbọ́n enia, yio si ma gbọ́n siwaju, kọ́ enia olõtọ, yio si ma fẹ ọ.
10. Ibẹ̀ru Oluwa ni ipilẹṣẹ ọgbọ́n: ati ìmọ Ẹni-Mimọ́ li oye.
11. Nitori nipasẹ mi li ọjọ rẹ yio ma lé si i, ati ọdun ìye rẹ yio si ma lé si i.
12. Bi iwọ ba gbọ́n, iwọ o gbọ́n fun ara rẹ: ṣugbọn bi iwọ ba iṣe ẹlẹgàn, iwọ nikan ni yio rù u.
13. Alaroye li aṣiwere obinrin: òpe ni kò si mọ̀ nkan.