9. Gbangba ni gbogbo wọn jasi fun ẹniti o yé, o si tọ́ fun awọn ti o nwá ìmọ ri.
10. Gbà ẹkọ mi, kì si iṣe fadaka; si gbà ìmọ jù wura àṣayan lọ.
11. Nitori ti ìmọ jù iyùn lọ; ohun gbogbo ti a le fẹ, kò si eyi ti a le fi we e.
12. Emi ọgbọ́n li o mba imoye gbe, emi ìmọ si ri imoye ironu.
13. Ibẹ̀ru Oluwa ni ikorira ibi: irera, ati igberaga, ati ọ̀na ibi, ati ẹnu arekereke, ni mo korira.
14. Temi ni ìmọ ati ọgbọ́n ti o yè: emi li oye, emi li agbara.
15. Nipasẹ mi li ọba nṣe akoso, ti awọn olori si nlàna otitọ.
16. Nipasẹ mi li awọn ijoye nṣolori, ati awọn ọ̀lọtọ̀, ani gbogbo awọn onidajọ aiye.