Owe 8:20-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Emi nrìn li ọ̀na ododo, larin ipa-ọ̀na idajọ:

21. Ki emi ki o le mu awọn ti o fẹ mi jogun ohun-ini mi, emi o si fi kún iṣura wọn.

22. Oluwa pèse mi ni ipilẹṣẹ ìwa rẹ̀, ṣaju iṣẹ rẹ̀ atijọ.

23. A ti yàn mi lati aiyeraiye, lati ipilẹṣẹ, tabi ki aiye ki o to wà.

24. Nigbati ọgbun kò si, a ti bi mi; nigbati kò si orisun ti o kún fun omi pipọ.

25. Ki a to fi idi awọn òke-nla sọlẹ, ṣãju awọn òke li a ti bi mi:

26. Nigbati kò ti ida aiye, tabi pẹ̀tẹlẹ, tabi ori erupẹ aiye.

Owe 8