5. Gbà ara rẹ bi abo agbọnrin li ọwọ ọdẹ, ati bi ẹiyẹ li ọwọ apẹiyẹ.
6. Tọ ẽrùn lọ, iwọ ọlẹ: kiyesi iṣe rẹ̀ ki iwọ ki o si gbọ́n:
7. Ti kò ni onidajọ, alabojuto, tabi alakoso.
8. Ti npese onjẹ rẹ̀ ni igba-ẹ̀run, ti o si nkó onjẹ rẹ̀ jọ ni ìgba ikore.
9. Ọlẹ, iwọ o ti sùn pẹ to? nigbawo ni iwọ o dide kuro ninu orun rẹ?
10. Orun diẹ si i, õgbe diẹ si i, ikawọkòpọ lati sùn diẹ:
11. Bẹ̃ni òṣi rẹ yio de bi ẹniti nrìn àjo, ati aini rẹ bi ọkunrin ti o hamọra ogun.
12. Enia-kenia, ọkunrin buburu, ti o nrìn ti on ti ẹnu arekereke.
13. O nṣẹju rẹ̀, o nfi ẹsẹ rẹ̀ sọ̀rọ, o nfi ika rẹ̀ ṣe ajuwe;
14. Arekereke mbẹ li aiya rẹ̀, o humọ ìwa-ika nigbagbogbo; o ndá ija silẹ.
15. Nitorina ni ipọnju rẹ̀ yio de si i lojiji; ojiji ni yio ṣẹ́ laini atunṣe.
16. Ohun mẹfa li Oluwa korira: nitõtọ, meje li o ṣe irira fun ọkàn rẹ̀: