Owe 30:15-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Eṣúṣu ni ọmọbinrin meji, ti nkigbe pe, Muwá, muwá. Ohun mẹta ni mbẹ ti a kò le tẹ lọrùn lai, ani mẹrin kì iwipe, o to.

16. Isa-okú, ati inu àgan; ilẹ ti kì ikún fun omi; ati iná ti kì iwipe, o to.

17. Oju ti o sin baba rẹ̀ jẹ, ti o gàn ati gbọ́ ti iya rẹ̀, kanakáná ẹba odò ni yio yọ ọ jade, ọmọ idì a si mu u jẹ.

18. Ohun mẹta ni mbẹ ti o ṣe iyanu fun mi, nitõtọ, mẹrin li emi kò mọ̀.

19. Ipa idì loju ọrun; ipa ejò lori apata: ipa ọkọ̀ loju okun; ati ìwa ọkunrin pẹlu wundia.

20. Bẹ̃ni ìwa agbere obinrin: o jẹun, o si nù ẹnu rẹ̀ nù, o si wipe, emi kò ṣe buburu kan.

21. Nitori ohun mẹta, aiye a di rũru, ati labẹ mẹrin ni kò le duro.

22. Iranṣẹ, nigbati o jọba; ati aṣiwère, nigbati o yo fun onjẹ;

23. Fun obinrin, ti a korira, nigbati a sọ ọ di iyale; ati fun iranṣẹbinrin, nigbati o di arole iya rẹ̀.

24. Ohun mẹrin ni mbẹ ti o kerejù lori ilẹ, sibẹ nwọn gbọ́n, nwọn kọ́ni li ẹkọ́.

25. Alailagbara enia li ẽra, ṣugbọn nwọn a pese onjẹ wọn silẹ ni ìgba ẹ̀run.

26. Alailagbara enia li ehoro, ṣugbọn nwọn a ṣe ìho wọn ni ibi palapala okuta.

27. Awọn ẽṣú kò li ọba, sibẹ gbogbo wọn a jade lọ li ọwọ́-ọwọ́;

Owe 30