Owe 28:8-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ẹniti o fi elé ati ère aiṣõtọ sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di pupọ, o kó o jọ fun ẹniti yio ṣãnu fun awọn talaka.

9. Ẹniti o mu eti rẹ̀ kuro lati gbọ́ ofin, ani adura rẹ̀ pãpa yio di irira.

10. Ẹnikẹni ti o mu olododo ṣìna si ọ̀na buburu, ontikararẹ̀ yio bọ si iho, ṣugbọn aduro-ṣinṣin yio jogun ohun rere.

11. Ọlọrọ̀ gbọ́n li oju ara rẹ̀: ṣugbọn talaka ti o moye ridi rẹ̀.

12. Nigbati awọn olododo enia ba nyọ̀, ọṣọ́ nla a wà; ṣugbọn nigbati enia buburu ba dide, enia a sá pamọ́.

Owe 28