Owe 28:17-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Enia ti o ba hù ìwa-ika si ẹ̀jẹ ẹnikeji, yio sá lọ si ihò: ki ẹnikan ki o máṣe mu u.

18. Ẹnikẹni ti o ba nrin dẽde ni yio là: ṣugbọn ẹniti o nfi ayidayida rìn loju ọ̀na meji, yio ṣubu ninu ọkan ninu wọn.

19. Ẹniti o ba ro ilẹ rẹ̀ yio li ọ̀pọ onjẹ: ṣugbọn ẹniti o ba ntọ̀ enia asan lẹhin yio ni òṣi to.

20. Olõtọ enia yio pọ̀ fun ibukún: ṣugbọn ẹniti o kanju ati là kì yio ṣe alaijiya.

21. Iṣojuṣãju enia kò dara: nitoripe fun òkele onjẹ kan, ọkunrin na yio ṣẹ̀.

22. Ẹniti o kanju ati là, o li oju ilara, kò si rò pe òṣi mbọ̀wá ta on.

23. Ẹniti o ba enia wi yio ri ojurere ni ikẹhin jù ẹniti nfi ahọn pọn ọ lọ.

24. Ẹnikẹni ti o ba nja baba tabi iya rẹ̀ li ole, ti o si wipe, kì iṣe ẹ̀ṣẹ; on na li ẹgbẹ apanirun.

25. Ẹniti o ṣe agberaga li aiya, a rú ìja soke, ṣugbọn ẹniti o gbẹkẹ rẹ̀ le Oluwa li a o mu sanra.

Owe 28