Owe 23:13-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Máṣe fà ọwọ ibawi sẹhin kuro lara ọmọde, nitoripe bi iwọ ba fi paṣan nà a, on kì yio kú.

14. Iwọ fi paṣan nà a, iwọ o si gbà ọkàn rẹ̀ la kuro li ọrun-apadi.

15. Ọmọ mi, bi ọkàn rẹ ba gbọ́n ọkàn mi yio yọ̀, ani emi pẹlu.

16. Inu mi yio si dùn nigbati ètè rẹ ba nsọ̀rọ titọ.

17. Máṣe jẹ ki aiya rẹ ki o ṣe ilara si awọn ẹ̀lẹṣẹ, ṣugbọn ki iwọ ki o wà ni ibẹ̀ru Oluwa, li ọjọ gbogbo.

18. Nitoripe ikẹhin mbẹ nitõtọ; ireti rẹ kì yio si ke kuro.

19. Gbọ́, iwọ ọmọ mi, ki iwọ ki o si gbọ́n, ki iwọ ki o si ma tọ́ aiya rẹ si ọ̀na titọ.

20. Máṣe wà ninu awọn ọmuti; ninu awọn ti mba ẹran-ara awọn tikarawọn jẹ.

Owe 23