1. ORUKỌ rere sàn ni yiyàn jù ọrọ̀ pupọ lọ, ati ojurere ifẹ jù fadaka ati wura lọ.
2. Ọlọrọ̀ ati talaka pejọ pọ̀: Oluwa li ẹlẹda gbogbo wọn.
3. Ọlọgbọ́n enia ti ri ibi tẹlẹ, o si pa ara rẹ̀ mọ́: ṣugbọn awọn òpe a kọja, a si jẹ wọn niya.
4. Ere irẹlẹ ati ibẹ̀ru Oluwa li ọrọ̀, ọlá, ati ìye.
5. Ẹgún ati idẹkùn mbẹ li ọ̀na alayidayida: ẹniti o ba pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yio jina si wọn.