Owe 21:12-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Olododo kiyesi ile enia buburu: pe ẹnikan wà ti yio bì enia buburu ṣubu sinu iparun.

13. Ẹnikẹni ti o ba di eti rẹ̀ si igbe olupọnju, ontikararẹ̀ yio ke pẹlu: ṣugbọn a kì yio gbọ́.

14. Ọrẹ ikọkọ, o tù ibinu: ati ẹ̀bun ni iṣẹpo-aṣọ, o tù ibinu lile.

15. Ayọ̀ ni fun olododo lati ṣe idajọ: ṣugbọn iparun ni fun awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.

16. Ẹniti o ba yà kuro li ọ̀na oye, yio ma gbe inu ijọ awọn okú.

17. Ẹniti o ba fẹ afẹ, yio di talaka: ẹniti o fẹ ọti-waini pẹlu ororo kò le lọrọ̀.

Owe 21