Owe 19:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. TALAKA ti nrìn ninu ìwa-titọ rẹ̀, o san jù ẹniti o nṣe arekereke li ète rẹ̀ lọ, ti o si nṣe wère.

2. Pẹlupẹlu, ọkàn laini ìmọ, kò dara; ẹniti o ba si fi ẹsẹ rẹ̀ yara yio ṣubu.

3. Wère enia yi ọ̀na rẹ̀ po: nigbana ni aiya rẹ̀ binu si Oluwa.

Owe 19