Owe 18:5-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Kò dara lati ṣe ojuṣãju enia-buburu, lati bì olododo ṣubu ni idajọ.

6. Ete aṣiwère bọ sinu ìja, ẹnu rẹ̀ a si ma pè ìna wá.

7. Ẹnu aṣiwère ni iparun rẹ̀, ète rẹ̀ si ni ikẹkùn ọkàn rẹ̀.

8. Ọ̀rọ olofofo dabi adidùn, nwọn a si wọ isalẹ inu lọ.

9. Ẹniti o lọra pẹlu ni iṣẹ rẹ̀, arakunrin jẹguduragudu enia ni.

10. Orukọ Oluwa, ile-iṣọ agbara ni: Olododo sá wọ inu rẹ̀, o si là.

Owe 18