1. ỌLUKULUKU ọlọgbọ́n obinrin ni kọ́ ile rẹ̀: ṣugbọn aṣiwere a fi ọwọ ara rẹ̀ fà a lulẹ.
2. Ẹniti o nrìn ni iduroṣiṣin rẹ̀ o bẹ̀ru Oluwa: ṣugbọn ẹniti o ṣe arekereke li ọ̀na rẹ̀, o gàn a.
3. Li ẹnu aṣiwere ni paṣan igberaga; ṣugbọn ète awọn ọlọgbọ́n ni yio pa wọn mọ́.