Oni 8:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. TALI o dabi ọlọgbọ́n enia? tali o si mọ̀ itumọ nkan? Ọgbọ́n enia mu oju rẹ̀ dán, ati igboju rẹ̀ li a o si yipada.

2. Mo ba ọ mọ̀ ọ pe, ki iwọ ki o pa ofin ọba mọ́, eyini si ni nitori ibura Ọlọrun.

3. Máṣe yara ati jade kuro niwaju rẹ̀: máṣe duro ninu ohun buburu; nitori ohun ti o wù u ni iṣe.

4. Nibiti ọ̀rọ ọba gbe wà, agbara mbẹ nibẹ; tali o si le wi fun u pe, kini iwọ nṣe nì?

5. Ẹnikẹni ti o pa ofin mọ́ kì yio mọ̀ ohun buburu: aiya ọlọgbọ́n enia si mọ̀ ìgba ati àṣa.

6. Nitoripe ohun gbogbo ti o wuni ni ìgba ati àṣa wà fun, nitorina òṣi enia pọ̀ si ori ara rẹ̀.

7. Nitoriti kò mọ̀ ohun ti mbọ̀: tali o si le wi fun u bi yio ti ri?

8. Kò si enia kan ti o lagbara lori ẹmi lati da ẹmi duro; bẹ̃ni kò si lagbara li ọjọ ikú: kò si iránpada ninu ogun na; bẹ̃ni ìwa buburu kò le gbà awọn oluwa rẹ̀.

9. Gbogbo nkan wọnyi ni mo ri, mo si fiyè si iṣẹ gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn: ìgba kan mbẹ ninu eyi ti ẹnikan nṣe olori ẹnikeji fun ifarapa rẹ̀.

10. Bẹ̃ni mo si ri isinkú enia buburu, ati awọn ti o ṣe otitọ ti o wá ti o si lọ kuro ni ibi mimọ́, a si gbagbe wọn ni ilu na: asan li eyi pẹlu.

11. Nitoriti a kò mu idajọ ṣẹ kánkán si iṣẹ buburu, nitorina aiya awọn ọmọ enia mura pãpa lati huwa ibi.

Oni 8