Oni 7:5-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. O san lati gbọ́ ibawi ọlọgbọ́n jù ki enia ki o fetisi orin aṣiwère.

6. Nitoripe bi itapàpa ẹgún labẹ ìkoko, bẹ̃li ẹrín aṣiwère: asan li eyi pẹlu.

7. Nitõtọ inilara mu ọlọgbọ́n enia sinwin; ọrẹ a si ba aiya jẹ.

Oni 7