13. Ibi buburu kan mbẹ ti mo ri labẹ õrùn, eyini ni pe, ọrọ̀ ti a pamọ́ fun ifarapa awọn ti o ni i.
14. Nitori ọrọ̀ wọnni a ṣegbe nipa iṣẹ buburu; bi o si bi ọmọkunrin kan, kò ni nkan lọwọ rẹ̀.
15. Bi o ti ti inu iya rẹ̀ jade wá, ihoho ni yio si tun pada lọ bi o ti wá, kì yio si mu nkan ninu lãla rẹ̀, ti iba mu lọ lọwọ rẹ̀.
16. Ibi buburu li eyi pẹlu, pe li ọ̀na gbogbo, bi o ti wá, bẹ̃ni yio si lọ: ère ki si ni fun ẹniti nṣe lãla fun afẹfẹ?