2. Nitorina mo yìn okú ti o ti kú pẹ jù awọn alãye ti o wà lãye sibẹ.
3. Nitõtọ, ẹniti kò ti isi san jù awọn mejeji; ẹniti kò ti iri iṣẹ buburu ti a nṣe labẹ õrùn.
4. Ati pẹlu, mo rò gbogbo lãla ati ìmọ iṣẹ gbogbo, pe eyiyi ni ilara ẹnikini lati ọdọ ẹnikeji rẹ̀. Asan li eyi pẹlu ati imulẹmofo.
5. Aṣiwère fọwọ rẹ̀ lọwọ, o si njẹ ẹran-ara rẹ̀.
6. Onjẹ ikunwọ kan pẹlu idakẹjẹ, o san jù ikunwọ meji lọ ti o kun fun lãla ati imulẹmofo.