10. Nitoripe bi nwọn ba ṣubu, ẹnikini yio gbe ọ̀gba rẹ̀ dide: ṣugbọn egbe ni fun ẹniti o ṣe on nikan nigbati o ba ṣubu; ti kò li ẹlomiran ti yio gbé e dide.
11. Ati pẹlu, bi ẹni meji ba dubulẹ pọ̀, nigbana ni nwọn o mõru: ṣugbọn ẹnikan yio ha ti ṣe mõru?
12. Bi ẹnikan ba kọlu ẹnikan, ẹni meji yio kò o loju; ati okùn onikọ mẹta kì iyá fàja.
13. Otoṣi ipẹ̃rẹ ti o ṣe ọlọgbọ́n, o san jù arugbo ati aṣiwère ọba lọ ti kò mọ̀ bi a ti igbà ìmọran.
14. Nitoripe lati inu tubu li o ti jade wá ijọba; bi a tilẹ ti bi i ni talaka ni ijọba rẹ̀.
15. Mo ri gbogbo alãye ti nrìn labẹ õrun, pẹlu ipẹ̃rẹ ekeji ti yio dide duro ni ipò rẹ̀.