20. Nibikanna ni gbogbo wọn nlọ; lati inu erupẹ wá ni gbogbo wọn, gbogbo wọn si tun pada di erupẹ.
21. Tali o mọ̀ ẹmi ọmọ enia ti ngoke si apa òke, ati ẹmi ẹran ti nsọkalẹ si isalẹ ilẹ?
22. Nitorina mo woye pe kò si ohun ti o dara jù ki enia ki o ma yọ̀ ni iṣẹ ara rẹ̀; nitori eyini ni ipin rẹ̀: nitoripe tani yio mu u wá ri ohun ti yio wà lẹhin rẹ̀.