Oni 3:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUKULÙKU ohun li akoko wà fun, ati ìgba fun iṣẹ gbogbo labẹ ọrun.

2. Ìgba bibini, ati ìgba kikú, ìgba gbigbin ati ìgba kika ohun ti a gbin;

3. Ìgba pipa ati ìgba imularada; ìgba wiwo lulẹ ati ìgba kikọ;

4. Ìgba sisọkun ati ìgba rirẹrín; ìgba ṣiṣọ̀fọ ati igba jijo;

5. Ìgba kikó okuta danu, ati ìgba kiko okuta jọ; ìgba fifọwọkoni mọra, ati ìgba fifasẹhin ni fifọwọkoni mọra;

Oni 3