4. Ti ilẹkun yio si se ni igboro, nigbati iró ọlọ yio rẹlẹ, ti yio si dide li ohùn kike ẹiyẹ, ati ti gbogbo awọn ọmọbinrin orin yio rẹ̀ silẹ;
5. Ati pẹlu ti nwọn o bẹ̀ru ibi ti o ga, ti iwariri yio si wà li ọ̀na, ati ti igi almondi yio tanna, ti ẹlẹnga yio di ẹrù, ti ifẹ yio si ṣá: nitoriti ọkunrin nlọ si ile rẹ̀ pipẹ, awọn aṣọ̀fọ yio si ma yide kakiri.
6. Tabi ki okùn fadaka ki o to tu, tabi ki ọpọn wura ki o to fọ, tabi ki ìṣa ki o to fọ nibi isun, tabi ki ayika-kẹkẹ ki o to kán nibi kanga.
7. Nigbana ni erupẹ yio pada si ilẹ bi o ti wà ri, ẹmi yio si pada tọ̀ Ọlọrun ti o fi i funni.