Oba 1:18-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Ile Jakobu yio si jẹ iná, ati ile Josefu ọwọ́-iná, ati ile Esau fun akeku-koriko, nwọn o si ràn ninu wọn, nwọn o si run wọn; kì yio si sí ẹniti yio kù ni ile Esau: nitori Oluwa ti wi i.

19. Awọn ara gusu yio ni oke Esau; awọn ti pẹ̀tẹlẹ yio si ni awọn ara Filistia: nwọn o si ni oko Efraimu, ati oko Samaria: Benjamini yio si ni Gileadi.

20. Ati igbèkun ogun yi, ti awọn ọmọ Israeli ti o wà larin awọn ara Kenaani, titi de Sarefati; ati igbèkun Jerusalemu ti o wà ni Sefaradi, yio ni awọn ilu nla gusu.

21. Awọn olugbala yio si goke Sioni wá lati ṣe idajọ oke Esau; ijọba na yio si jẹ ti Oluwa.

Oba 1