O. Sol 8:4-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Mo fi nyin bu, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ki ẹ máṣe rú olufẹ mi soke, ki ẹ má si ṣe ji i, titi yio fi wù u.

5. Tani eyi ti ngòke lati aginju wá, ti o fi ara tì olufẹ rẹ̀? mo ji ọ dide labẹ igi eleso: nibẹ ni iya rẹ gbe bi ọ si, nibẹ li ẹniti o bi ọ gbe bi ọ si.

6. Gbe mi ka aiya rẹ bi edidi, bi edidi le apá rẹ: nitori ifẹ lagbara bi ikú; ijowu si le bi isa-okú; jijo rẹ̀ dabi jijo iná, ani ọwọ iná Oluwa.

7. Omi pupọ kò le paná ifẹ, bẹ̃ni kikún omi kò le gbá a lọ, bi enia fẹ fi gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ fun ifẹ, a o kẹgàn rẹ̀ patapata.

O. Sol 8