1. IWỌ iba jẹ dabi arakunrin fun mi, ti o mu ọmú iya mi! emi iba ri ọ lode emi iba fi ẹnu kò ọ lẹnu; lõtọ, nwọn kì ba fi mi ṣe ẹlẹya.
2. Emi iba fọnahàn ọ, emi iba mu ọ wá sinu ile iya mi, iwọ iba kọ́ mi: emi iba mu ọ mu ọti-waini õrùn didùn, ati oje eso granate mi.
3. Ọwọ osì rẹ̀ iba wà labẹ ori mi, ọwọ ọtún rẹ̀ iba si gbá mi mọra.
4. Mo fi nyin bu, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ki ẹ máṣe rú olufẹ mi soke, ki ẹ má si ṣe ji i, titi yio fi wù u.