9. Olufẹ mi dabi abo egbin, tabi ọmọ agbọnrin: sa wò o, o duro lẹhin ogiri wa, o yọju loju ferese, o nfi ara rẹ̀ hàn loju ferese ọlọnà.
10. Olufẹ mi sọ̀rọ, o si wi fun mi pe, Dide, olufẹ mi, arẹwà mi kanna, ki o si jade kalọ.
11. Sa wò o, ìgba otutu ti kọja, òjo ti da, o si ti lọ.
12. Awọn itanna eweko farahàn lori ilẹ; akoko ikọrin awọn ẹiyẹ de, a si gbọ ohùn àdaba ni ilẹ wa.