9. Ẹniti o gbin eti, o le ṣe alaigbọ́ bi? ẹniti o da oju, o ha le ṣe alairiran?
10. Ẹniti nnà awọn orilẹ-ède, o ha le ṣe alaiṣe olutọ́? on li ẹniti nkọ́ enia ni ìmọ.
11. Oluwa mọ̀ ìro-inu enia pe: asan ni nwọn.
12. Ibukún ni fun enia na ẹniti iwọ nà, Oluwa, ti iwọ si kọ́ lati inu ofin rẹ wá;
13. Ki iwọ ki o le fun u ni isimi kuro li ọjọ ibi, titi a o fi wà iho silẹ fun enia buburu.
14. Nitoripe Oluwa kì yio ṣa awọn enia rẹ̀ tì, bẹ̃ni kì yio kọ̀ awọn enia-ini rẹ̀ silẹ.
15. Ṣugbọn idajọ yio pada si ododo: gbogbo ọlọkàn diduro ni yio si ma tọ̀ ọ lẹhin.