O. Daf 94:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA, Ọlọrun ẹsan; Ọlọrun ẹsan, fi ara rẹ hàn.

2. Gbé ara rẹ soke, iwọ onidajọ aiye: san ẹsan fun awọn agberaga.

3. Oluwa, yio ti pẹ to ti awọn enia buburu, yio ti pẹ to ti awọn enia buburu yio fi ma leri?

4. Nwọn o ti ma dà ọ̀rọ nù ti nwọn o ma sọ ohun lile pẹ to? ti gbogbo oniṣẹ ẹ̀ṣẹ yio fi ma fi ara wọn leri.

5. Oluwa, nwọn fọ́ awọn enia rẹ tutu, nwọn si nyọ awọn enia-ini rẹ lẹnu.

6. Nwọn pa awọn opó ati alejo, nwọn si pa awọn ọmọ alaini-baba.

7. Sibẹ nwọn wipe, Oluwa kì yio ri i, bẹ̃li Ọlọrun Jakobu kì yio kà a si,

8. Ki oye ki o ye nyin, ẹnyin ope ninu awọn enia: ati ẹnyin aṣiwere, nigbawo li ẹnyin o gbọ́n?

9. Ẹniti o gbin eti, o le ṣe alaigbọ́ bi? ẹniti o da oju, o ha le ṣe alairiran?

10. Ẹniti nnà awọn orilẹ-ède, o ha le ṣe alaiṣe olutọ́? on li ẹniti nkọ́ enia ni ìmọ.

O. Daf 94