O. Daf 87:4-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Emi o da orukọ Rahabu ati Babeli lãrin awọn ti o mọ̀ mi: kiyesi Filistia ati Tire, pẹlu Etiopia: a bi eleyi nibẹ.

5. Ati ni Sioni li a o wipe: ọkunrin yi ati ọkunrin nì li a bi ninu rẹ̀: ati Ọga-ogo tikararẹ̀ ni yio fi ẹsẹ rẹ̀ mulẹ.

6. Oluwa yio kà, nigbati o ba nkọ orukọ awọn enia, pe, a bi eleyi nibẹ.

7. Ati awọn olorin ati awọn ti nlu ohun-elo orin yio wipe: Gbogbo orisun mi mbẹ ninu rẹ.

O. Daf 87