O. Daf 78:67-72 Yorùbá Bibeli (YCE)

67. Pẹlupẹlu o kọ̀ agọ Josefu, kò si yàn ẹ̀ya Efraimu:

68. Ṣugbọn o yan ẹ̀ya Juda, òke Sioni ti o fẹ.

69. O si kọ́ ibi-mimọ́ rẹ̀ bi òke-ọrun bi ilẹ ti o ti fi idi rẹ̀ mulẹ lailai.

70. O si yàn Dafidi iranṣẹ rẹ̀, o si mu u kuro lati inu agbo-agutan wá:

71. Lati má tọ̀ awọn agutan lẹhin, ti o tobi fun oyun, o mu u lati ma bọ́ Jakobu, enia rẹ̀, ati Israeli, ilẹ-ini rẹ̀.

72. Bẹ̃li o bọ́ wọn gẹgẹ bi ìwa-titọ inu rẹ̀; o si fi ọgbọ́n ọwọ rẹ̀ ṣe amọna wọn.

O. Daf 78