61. O si fi agbara rẹ̀ fun igbekun, ati ogo rẹ̀ le ọwọ ọta nì.
62. O fi awọn enia rẹ̀ fun idà pẹlu; o si binu si ilẹ-ini rẹ̀.
63. Iná run awọn ọdọmọkunrin wọn; a kò si fi orin sin awọn wundia wọn ni iyawo.
64. Awọn alufa wọn ti oju idà ṣubu; awọn opó wọn kò si pohunrere ẹkún.
65. Nigbana li Oluwa ji bi ẹnipe loju orun, ati bi alagbara ti o nkọ nitori ọti-waini.
66. O si kọlu awọn ọta rẹ̀ lẹhin; o sọ wọn di ẹ̀gan titi aiye.