O. Daf 78:54-61 Yorùbá Bibeli (YCE)

54. O si mu wọn wá si eti ibi-mimọ́ rẹ̀, ani si òke yi ti ọwọ ọtún rẹ̀ ti rà.

55. O tì awọn keferi jade pẹlu kuro niwaju wọn, o si fi tita okùn pinlẹ fun wọn ni ilẹ-ini, o si mu awọn ẹya Israeli joko ninu agọ wọn.

56. Ṣugbọn nwọn dan a wò, nwọn si ṣọ̀tẹ si Ọlọrun Ọga-ogo, nwọn kò si pa ẹri rẹ̀ mọ́.

57. Ṣugbọn nwọn yipada, nwọn ṣe alaiṣotitọ bi awọn baba wọn: nwọn si pẹhinda si apakan bi ọrun ẹ̀tan.

58. Nitori ti nwọn fi ibi giga wọn bi i ninu, nwọn si fi ere finfin wọn mu u jowu.

59. Nigbati Ọlọrun gbọ́ eyi, o binu, o si korira Israeli gidigidi.

60. Bẹ̃li o kọ̀ agọ Ṣilo silẹ, agọ ti o pa ninu awọn enia.

61. O si fi agbara rẹ̀ fun igbekun, ati ogo rẹ̀ le ọwọ ọta nì.

O. Daf 78