4. Awọn ọta rẹ nke ramu-ramu lãrin ijọ enia rẹ; nwọn gbé asia wọn soke fun àmi.
5. Nwọn dabi ọkunrin ti ngbé akeke rẹ̀ soke ninu igbo didi,
6. Ṣugbọn nisisiyi iṣẹ ọnà finfin ni nwọn fi akeke ati òlu wó lulẹ pọ̀ li ẹ̃kan.
7. Nwọn tinabọ ibi-mimọ́ rẹ, ni wiwo ibujoko orukọ rẹ lulẹ, nwọn sọ ọ di ẽri.