O. Daf 72:14-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. On o rà ọkàn wọn pada lọwọ ẹ̀tan ati ìwa-agbara: iyebiye si li ẹ̀jẹ wọn li oju rẹ̀.

15. On o si yè, on li a o si fi wura Ṣeba fun: a o si ma gbadura fun u nigbagbogbo: lojojumọ li a o si ma yìn i.

16. Ikúnwọ ọkà ni yio ma wà lori ilẹ, lori awọn òke nla li eso rẹ̀ yio ma mì bi Lebanoni: ati awọn ti inu ilu yio si ma gbà bi koriko ilẹ.

17. Orukọ rẹ̀ yio wà titi lai: orukọ rẹ̀ yio ma gbilẹ niwọn bi õrun yio ti pẹ to: nwọn o si ma bukún fun ara wọn nipaṣẹ rẹ̀: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio ma pè e li alabukúnfun.

18. Olubukún li Oluwa Ọlọrun, Ọlọrun Israeli, ẹnikanṣoṣo ti nṣe ohun iyanu.

O. Daf 72