O. Daf 71:11-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Nwọn wipe, Ọlọrun ti kọ̀ ọ silẹ: ẹ lepa ki ẹ si mu u; nitori ti kò si ẹniti yio gbà a.

12. Ọlọrun, máṣe jina si mi: Ọlọrun mi, yara si iranlọwọ mi.

13. Jẹ ki nwọn ki o dãmu, ki a si run awọn ti nṣe ọta ọkàn mi, ki a si fi ẹ̀gan ati àbuku bo awọn ti nwá ifarapa mi.

14. Ṣugbọn emi o ma reti nigbagbogbo, emi o si ma fi iyìn kún iyìn rẹ.

15. Ẹnu mi yio ma fi ododo rẹ ati igbala rẹ hàn li ọjọ gbogbo; emi kò sa mọ̀ iye rẹ̀.

16. Emi o wá li agbara Oluwa Ọlọrun; emi o ma da ọ̀rọ ododo rẹ sọ, ani tirẹ nikan.

17. Ọlọrun, iwọ ti kọ́ mi lati igba ewe mi wá: ati di isisiyi li emi ti nsọ̀rọ iṣẹ iyanu rẹ.

O. Daf 71