O. Daf 69:32-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Awọn onirẹlẹ yio ri eyi, inu wọn o si dùn: ọkàn ẹnyin ti nwá Ọlọrun yio si wà lãye.

33. Nitoriti Oluwa gbohùn awọn talaka, kò si fi oju pa awọn ara tubu rẹ̀ rẹ́.

34. Jẹ ki ọrun on aiye ki o yìn i, okun ati ohun gbogbo ti nrakò ninu wọn.

35. Nitoriti Ọlọrun yio gbà Sioni là, yio si kọ́ ilu Juda wọnni: ki nwọn ki o le ma gbe ibẹ, ki nwọn ki o le ma ni i ni ilẹ-ini.

36. Iru-ọmọ awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu ni yio ma jogun rẹ̀: awọn ti o si fẹ orukọ rẹ̀ ni yio ma gbe inu rẹ̀.

O. Daf 69