1. ẸNYIN ha nsọ ododo nitõtọ, ẹnyin ijọ enia? ẹnyin ha nṣe idajọ ti o ṣe titọ, ẹnyin ọmọ enia?
2. Nitõtọ, ẹnyin nṣiṣẹ buburu li aiya; ẹnyin nwọ̀n ìwa-agbara ọwọ nyin li aiye.
3. Lati inu iya wọn wá li awọn enia buburu ti ṣe iyapa: nwọn ti ṣina lojukanna ti a ti bi wọn, nwọn a ma ṣeke.
4. Oró wọn dabi oró ejò: nwọn dabi aditi ejò pamọlẹ ti o di ara rẹ̀ li eti;
5. Ti kò fẹ igbọ́ ohùn awọn atuniloju, bi o ti wù ki o ma fi ọgbọ́n ṣe ituju to.
6. Ká wọn li ehin, Ọlọrun, li ẹnu wọn: ká ọ̀gan awọn ọmọ kiniun nì, Oluwa.