6. Emi si wipe, A! iba ṣe pe emi ni iyẹ-apa bi àdaba! emi iba fò lọ, emi a si simi.
7. Kiyesi i, emi iba rìn lọ si ọ̀na jijin rére, emi a si ma gbe li aginju.
8. Emi iba yara sa asala mi kuro ninu ẹfufu lile ati iji na.
9. Oluwa, ṣe iparun, ki o si yà wọn li ahọn: nitori ti mo ri ìwa agbara ati ijà ni ilu na.
10. Ọsan ati oru ni nwọn fi nrìn odi rẹ̀ kiri: ìwa-ika pẹlu ati ikãnu mbẹ li arin rẹ̀.