O. Daf 45:3-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. San idà rẹ mọ idi rẹ, Alagbara julọ, ani ogo rẹ ati ọlá-nla rẹ.

4. Ati ninu ọlánlá rẹ ma gẹṣin lọ li alafia, nitori otitọ ati ìwa-tutu ati ododo; ọwọ ọtún rẹ yio si kọ́ ọ li ohun ẹ̀ru.

5. Ọfa rẹ mu li aiya awọn ọta ọba; awọn enia nṣubu nisalẹ ẹsẹ rẹ.

6. Ọlọrun, lai ati lailai ni itẹ́ rẹ: ọpá-alade ijọba rẹ, ọpá-alade otitọ ni.

7. Iwọ fẹ ododo, iwọ korira ìwa-buburu: nitori na li Ọlọrun, Ọlọrun rẹ, ṣe fi àmi ororo ayọ̀ yà ọ ṣolori awọn ọ̀gba rẹ.

8. Gbogbo aṣọ rẹ li o nrun turari, ati aloe, ati kassia, lati inu ãfin ehin-erin jade ni nwọn gbe nmu ọ yọ̀.

9. Awọn ọmọbinrin awọn alade wà ninu awọn ayanfẹ rẹ: li ọwọ ọtún rẹ li ayaba na gbe duro ninu wura Ofiri.

O. Daf 45