O. Daf 44:3-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Nitoriti nwọn kò ni ilẹ na nipa idà ara wọn, bẹ̃ni kì iṣe apá wọn li o gbà wọn; bikoṣe ọwọ ọtún rẹ ati apá rẹ, ati imọlẹ oju rẹ, nitoriti iwọ ni ifẹ rere si wọn.

4. Iwọ li Ọba mi, Ọlọrun: paṣẹ igbala fun Jakobu.

5. Nipasẹ̀ rẹ li awa o bì awọn ọta wa ṣubu: nipasẹ orukọ rẹ li awa o tẹ̀ awọn ti o dide si wa mọlẹ.

6. Nitoriti emi kì yio gbẹkẹle ọrun mi, bẹ̃ni idà mi kì yio gbà mi.

7. Ṣugbọn iwọ li o ti gbà wa lọwọ awọn ọta wa, iwọ si ti dojutì awọn ti o korira wa.

8. Niti Ọlọrun li awa nkọrin iyìn li ọjọ gbogbo, awa si nyìn orukọ rẹ lailai.

9. Ṣugbọn iwọ ti ṣa wa tì, iwọ si ti dojutì wa: iwọ kò si ba ogun wa jade lọ.

10. Iwọ mu wa pẹhinda fun ọta wa: ati awọn ti o korira wa nṣe ikogun fun ara wọn.

11. Iwọ ti fi wa fun jijẹ bi ẹran agutan; iwọ si ti tú wa ka ninu awọn keferi.

12. Iwọ ti tà awọn enia rẹ li asan, iwọ kò si fi iye-owo wọn sọ ọrọ̀ rẹ di pupọ.

13. Iwọ sọ wa di ẹ̀gan si awọn aladugbo wa, ẹlẹya ati iyọṣutì-si, si awọn ti o yi ni ka.

14. Iwọ sọ wa di ẹni-owe ninu awọn orilẹ-ède, ati imirisi ninu awọn enia.

15. Idamu mi mbẹ niwaju mi nigbagbogbo, itiju mi si bò mi mọlẹ.

16. Nitori ohùn ẹniti ngàn, ti o si nsọ̀rọ buburu; nitori ipa ti ọta olugbẹsan nì.

17. Gbogbo wọnyi li o de si wa; ṣugbọn awa kò gbagbe rẹ, bẹ̃li awa kò ṣe eke si majẹmu rẹ.

O. Daf 44