O. Daf 43:3-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Rán imọlẹ rẹ ati otitọ rẹ jade, ki nwọn ki o ma ṣe amọna mi: ki nwọn ki o mu mi gùn òke mimọ́ rẹ, ati sinu agọ rẹ wọnni.

4. Nigbana li emi o lọ si ibi pẹpẹ Ọlọrun, sọdọ Ọlọrun ayọ̀ nla mi: nitõtọ, lara duru li emi o ma yìn ọ, Ọlọrun, Ọlọrun mi.

5. Ẽṣe ti ori rẹ fi tẹ̀ba, iwọ ọkàn mi? ẽṣe ti ara rẹ kò fi lelẹ ninu mi? iwọ ṣe ireti niti Ọlọrun: nitoriti emi o sa ma yìn i sibẹ, ẹniti iṣe iranlọwọ oju mi, ati Ọlọrun mi.

O. Daf 43