O. Daf 41:4-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Emi wipe, Oluwa ṣãnu fun mi: mu ọkàn mi lara da; nitori ti mo ti ṣẹ̀ si ọ.

5. Awọn ọta mi nsọ ibi si mi pe, nigbawo ni on o kú, ti orukọ rẹ̀ yio si run?

6. Bi o ba si wá wò mi, on a ma sọ̀rọ ẹ̀tan: aiya rẹ̀ kó ẹ̀ṣẹ jọ si ara rẹ̀; nigbati o ba jade lọ, a ma wi i.

7. Gbogbo awọn ti o korira mi jumọ nsọ̀rọ kẹlẹ́ si mi: emi ni nwọn ngbìmọ ibi si.

8. Pe, ohun buburu li o dì mọ ọ ṣinṣin: ati ibiti o dubulẹ si, kì yio dide mọ.

9. Nitõtọ ọrẹ-iyọrẹ ara mi, ẹniti mo gbẹkẹle, ẹniti njẹ ninu onjẹ mi, o gbe gigisẹ rẹ̀ si mi.

10. Ṣugbọn iwọ, Oluwa, ṣãnu fun mi, ki o si gbé mi dide, ki emi ki o le san a fun wọn.

11. Nipa eyi ni mo mọ̀ pe iwọ ṣe oju-rere si mi, nitoriti awọn ọta mi kò yọ̀ mi.

12. Bi o ṣe ti emi ni, iwọ dì mi mu ninu ìwatitọ mi, iwọ si gbé mi kalẹ niwaju rẹ titi lai.

O. Daf 41