O. Daf 41:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. IBUKÚN ni fun ẹniti nrò ti awọn alaini, Oluwa yio gbà a ni ìgbà ipọnju.

2. Oluwa yio pa a mọ́, yio si mu u wà lãye; a o si bukún fun u lori ilẹ: iwọ kì yio si fi i le ifẹ awọn ọta rẹ̀ lọwọ.

3. Oluwa yio gbà a ni iyanju lori ẹní àrun: iwọ o tẹ ẹní rẹ̀ gbogbo ni ibulẹ arun rẹ̀.

4. Emi wipe, Oluwa ṣãnu fun mi: mu ọkàn mi lara da; nitori ti mo ti ṣẹ̀ si ọ.

O. Daf 41