O. Daf 40:5-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Oluwa Ọlọrun mi ọ̀pọlọpọ ni iṣẹ iyanu ti iwọ ti nṣe, ati ìro inu rẹ sipa ti wa: a kò le kà wọn fun ọ li ẹsẹ-ẹsẹ: bi emi o wi ti emi o sọ̀rọ wọn, nwọn jù ohun kikà lọ.

6. Ẹbọ ati ọrẹ iwọ kò fẹ: eti mi ni iwọ ti ṣi: ọrẹ-ẹbọ sisun, ati ọrẹ-ẹbọ ẹ̀ṣẹ on ni iwọ kò bère.

7. Nigbana ni mo wipe, Kiyesi i, emi de: ninu àpo-iwe nì li a gbe kọwe mi pe,

8. Inu mi dùn lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun mi, nitõtọ, ofin rẹ mbẹ li aiya mi.

9. Emi ti wãsu ododo ninu awujọ nla: kiyesi i, emi kò pa ete mi mọ́, Oluwa, iwọ mọ̀.

10. Emi kò fi ododo rẹ sin li aiya mi, emi o sọ̀rọ otitọ ati igbala rẹ: emi kò si pa iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ mọ́ kuro lọdọ ijọ nla nì.

11. Iwọ máṣe fa ãnu rẹ ti o rọnu sẹhin kuro lọdọ mi, Oluwa: ki iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ ki o ma pa mi mọ́ nigbagbogbo.

12. Nitoripe ainiye ibi li o yika kiri: ẹ̀ṣẹ mi dì mọ mi, bẹ̃li emi kò le gbé oju wò oke, nwọn jù irun ori mi lọ: nitorina aiya mi npá mi.

13. Ki o wù ọ, Oluwa, lati gbà mi: Oluwa, yara lati ràn mi lọwọ,

O. Daf 40