O. Daf 38:15-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Nitori, Oluwa, iwọ li emi duro dè, iwọ o gbọ́, Oluwa Ọlọrun mi.

16. Nitori ti mo wipe, Gbohùn mi, ki nwọn ki o má ba yọ̀ mi; nigbati ẹsẹ mi ba yọ́, nwọn o ma gbé ara wọn ga si mi.

17. Emi ti mura ati ṣubu, ikãnu mi si mbẹ nigbagbogbo niwaju mi.

18. Nitori ti emi o jẹwọ ẹ̀ṣẹ mi; emi o kãnu nitori ẹ̀ṣẹ mi.

O. Daf 38