30. Ẹnu olododo ni ima sọ̀rọ ọgbọ́n, ahọn rẹ̀ a si ma sọ̀rọ idajọ.
31. Ofin Ọlọrun rẹ̀ mbẹ li aiya rẹ̀; ọkan ninu ìrin rẹ̀ kì yio yẹ̀.
32. Ẹni buburu nṣọ olododo, o si nwá ọ̀na lati pa a.
33. Oluwa kì yio fi i le e lọwọ, kì yio si da a lẹbi, nigbati a ba nṣe idajọ rẹ̀.
34. Duro de Oluwa, ki o si ma pa ọ̀na rẹ̀ mọ́, yio si gbé ọ leke lati jogun aiye: nigbati a ba ké awọn enia buburu kuro, iwọ o ri i.
35. Emi ti nri enia buburu, ẹni ìwa-ika, o si fi ara rẹ̀ gbilẹ bi igi tutu nla.
36. Ṣugbọn o kọja lọ, si kiyesi i, kò sí mọ: lõtọ emi wá a kiri, ṣugbọn a kò le ri i.
37. Ma kiyesi ẹni pipé, ki o si ma wò ẹni diduro ṣinṣin: nitori alafia li opin ọkunrin na.
38. Ṣugbọn awọn alarekọja li a o parun pọ̀; iran awọn enia buburu li a o ké kuro.
39. Ṣugbọn lati ọwọ Oluwa wá ni igbala awọn olododo; on li àbo wọn ni igba ipọnju.