10. Gbọ́, Oluwa, ki o si ṣãnu fun mi: Oluwa, iwọ ma ṣe oluranlọwọ mi.
11. Iwọ ti sọ ikãnu mi di ijó fun mi; iwọ ti bọ aṣọ-ọ̀fọ mi kuro, iwọ si fi ayọ̀ dì mi li àmure.
12. Nitori idi eyi ni ki ogo mi ki o le ma kọrin si ọ, ki o má si ṣe dakẹ. Oluwa Ọlọrun mi, emi o ma fi iyìn fun ọ lailai.