O. Daf 27:6-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Nigbayi li ori mi yio gbé soke ga jù awọn ọta mi lọ, ti o yi mi ká, nitorina li emi o ṣe rubọ ayọ̀ ninu agọ rẹ̀; emi o kọrin, nitõtọ emi o kọrin iyìn si Oluwa.

7. Gbọ́, Oluwa, nigbati mo ba fi ohùn mi pè: ṣanu fun mi pẹlu, ki o si da mi li ohùn.

8. Nigbati o wipe, Ẹ ma wa oju mi; ọkàn mi wi fun ọ pe, Oju rẹ, Oluwa, li emi o ma wá.

9. Máṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lọdọ mi; máṣe fi ibinu ṣa iranṣẹ rẹ tì: iwọ li o ti nṣe iranlọwọ mi; má fi mi silẹ, bẹ̃ni ki o máṣe kọ̀ mi, Ọlọrun igbala mi.

10. Nigbati baba ati iya mi kọ̀ mi silẹ, nigbana ni Oluwa yio tẹwọgbà mi.

11. Kọ́ mi li ọ̀na rẹ, Oluwa, ki o si tọ́ mi li ọ̀na titọ, nitori awọn ọta mi.

12. Máṣe fi mi le ifẹ awọn ọta mi lọwọ; nitori awọn ẹlẹri eke dide si mi, ati iru awọn ti nmí imí-ìkà.

13. Ṣugbọn emi ti gbagbọ lati ri ire Oluwa ni ilẹ alãye.

14. Duro de Oluwa; ki o si tújuka, yio si mu ọ li aiya le: mo ni, duro de Oluwa.

O. Daf 27